Numbers 27:12-14

Joṣua láti rọ́pò Mose

12 aNígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. 13Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe, 14nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

Copyright information for YorBMYO